Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Àwọn ni olórí tí a yàn ninu àwọn ọmọ Israẹli, olukuluku wọn jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn, ati ní ìdílé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Wọnyi li awọn ti a yàn ninu ijọ, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:16
20 Iomraidhean Croise  

Ṣa àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n ṣe olórí: lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá.


Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá.


“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata, bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé.”


Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”


Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí


Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.


Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ.


Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú nínú Ẹ̀mí tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.


Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́tà-lé-nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí.


àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.


Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ:


Nígbà náà ni àwọn olórí Israẹli, àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn alábojútó àwọn tí a kà náà mú ọrẹ wá.


Bẹ́ẹ̀ ni mo yan olórí àwọn ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé, mo sì fi jẹ olórí yín: olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà yín.


Gideoni sì dáhùn pé, “Yéè olúwa mi, ọ̀nà wo ni èmi yóò fi gba Israẹli là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Manase, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.”


Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Benjamini, ọmọ Jese yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí?


Ẹ sì wò, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Israẹli, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Juda!”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan