Marku 8:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Faic an caibideilYoruba Bible6 Ó bá pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó ní ilẹ̀. Ó mú burẹdi meje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ6 O si paṣẹ ki awọn enia joko ni ilẹ: o si mu iṣu akara meje na, o dupẹ, o bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; nwọn si gbé e kalẹ niwaju awọn enia. Faic an caibideil |