Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 5:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ó ké rara pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ọmọ Ọlọrun tí ó lógo jùlọ? Mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 5:7
29 Iomraidhean Croise  

Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”


Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi yóò fi ọ bú pé kí o má ṣe sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”


Ìwọ Efraimu; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”


Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”


Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́. Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”


Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”


Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”


“Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”


Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́. Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?”


Ìgbàkúgbà tí àwọn tí ó ni ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú ri, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”


Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.


Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”


Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún:


“Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”


Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.


Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jesu, ìwọ ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.”


Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.


Òun náà ni ó ń tọ Paulu àti àwa lẹ́hìn, ó sì ń kígbe, pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yin!”


Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.”


Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitiisi?”


Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.


Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù.


Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salẹmu, àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un,


Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì.


Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́.


Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run.


Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì.


Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn. Ègbé ni fún ayé àti Òkun; nítorí èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú sá ni òun ní.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan