Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 4:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, “ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run. Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Kí wọn baà lè la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kí wọn má ríran; kí wọn gbọ́ títí ṣugbọn kí òye má yé wọn; kí wọn má baà ronupiwada, kí á má baà dáríjì wọ́n.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nitori ni ríri ki nwọn ki o le ri, ki nwọn má si kiyesi; ati ni gbigbọ́ ki nwọn ki o le gbọ́, ki o má si yé wọn; ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba dari jì wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 4:12
18 Iomraidhean Croise  

Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde, tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.


Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn; a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan; bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.


Ó lè jẹ́ wí pé ilé Juda yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn; kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀. Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.”


Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.


“Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.


Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?


Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí, “ ‘kí wọn má ba à rí, àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’


Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,


Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.


Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́,


láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan