Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 3:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 láti Idumea ati apá ìlà oòrùn odò Jọdani ati agbègbè Tire ati ti Sidoni. Ogunlọ́gọ̀ eniyan wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó ń ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 3:8
18 Iomraidhean Croise  

Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.


“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”


Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́.


Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Israẹli di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ. Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Seiri, ìwọ àti gbogbo ará Edomu. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa.’ ”


èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’


Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Koraṣini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.


Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri.


Nígbà náà ni Jesu fi agbègbè Tire àti Sidoni sílẹ̀, ó wá si Òkun Galili láàrín agbègbè Dekapoli.


Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn;


Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.


Ìlú ìpẹ̀kun gúúsù ti ẹ̀yà Juda ní gúúsù ní ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabṣeeli, Ederi, Jaguri,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan