Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 3:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mú un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́, wọ́n jáde lọ láti fi agbára mú un nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Nigbati awọn ibatan rẹ̀ si gbọ́ eyini, nwọn jade lọ lati mu u: nitoriti nwọn wipe, Ori rẹ̀ bajẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 3:21
8 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Jehu jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?” Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jehu fèsì.


‘Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jehoiada láti máa jẹ́ alákòóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.


Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀; àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni. A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀ A ka ẹni ìmísí sí asínwín.


Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìyá wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n ń pè é.


Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”


Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”


Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan