Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 13:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ṣugbọn a níláti kọ́kọ́ waasu ìyìn rere fún orílẹ̀-èdè gbogbo ná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 13:10
10 Iomraidhean Croise  

Àwọn ará Ninefe yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi. Nítorí pé wọ́n ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Jona wà níhìn-ín yìí.


A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.


Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìhìnrere mi fún gbogbo ẹ̀dá.


Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.


Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́: “Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.”


nípa agbára iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìhìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.


bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìhìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún.


èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìhìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.


Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan