Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 13:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Bí Jesu ti ń jáde láti inú tẹmpili ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Bí ó ti ń jáde kúrò ninu Tẹmpili, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olùkọ́ni, wo òkúta wọnyi ati ilé yìí, wò ó bí wọn ti tóbi tó!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 BI o si ti nti tẹmpili jade, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wipe, Olukọni, wò irú okuta ati irú ile ti o wà nihinyi!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 13:1
9 Iomraidhean Croise  

Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.


Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn.


Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa.


Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan