Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:44 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

44 Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

44 Ó wí fún un pé, “Má wí ohunkohun fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o sì rúbọ ìwòsàn rẹ bí Mose ti pàṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

44 O si wi fun u pe, Wo o, máṣe sọ ohunkohun fun ẹnikẹni: ṣugbọn lọ, fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si fi ẹ̀bun iwẹnumọ́ rẹ ti Mose ti palaṣẹ, ni ẹrí fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:44
9 Iomraidhean Croise  

Jesu sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnìkan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mose pàṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.”


Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi


Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.


Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.”


Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”


Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí.


Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan