Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:41 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

41 Àánú ṣe Jesu ó bá na ọwọ́ ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́. Di mímọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

41 Jesu ṣãnu rẹ̀, o nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o si wi fun u pe, Mo fẹ, iwọ di mimọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:41
12 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà.


Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.


Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.


Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”


Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.


Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́! Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.


Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró).


Bí Jesu ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.


Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.


Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.


Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan