Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Ó wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tí Satani ń dán an wò. Ààrin àwọn ẹranko ni ó wà, ṣugbọn àwọn angẹli ń ṣe iranṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 O si wà ni ogoji ọjọ ni ijù, a ti ọwọ́ Satani dán an wò, o si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ́; awọn angẹli si nṣe iranṣẹ fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:13
13 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.


Mose wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru (40) láìjẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.


Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) angẹli méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.


Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jesu sí ijù láti dán an wò láti ọwọ́ èṣù.


Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù;


Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, wàláà òkúta májẹ̀mú náà.


Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru: Èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú Olúwa, tí ẹ sì ń mú u bínú.


Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run.


Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fihàn nínú ara, tí a dá láre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn angẹli rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.


Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan