Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 8:53 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

53 Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

53 Ńṣe ni wọ́n ń fi Jesu rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

53 Nwọn si fi i ṣẹ̀fẹ, nwọn sa mọ̀ pe o kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 8:53
11 Iomraidhean Croise  

“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn: à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.


Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi, ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.


Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.


A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí. Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.


Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà.


Àwọn Farisi, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ ṣùtì sí i.


Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.”


Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!”


Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan