Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni Olúwa ti ó mú ọ láradá.”