Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 8:43 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

43 Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

43 Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

43 Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 8:43
22 Iomraidhean Croise  

Ní ọdún kọkàn-dínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.


Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀, oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.


Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú, nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.


Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́, èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀. Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?


Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”


Àti pé, nígbàkúgbà tí ó bá mú un, á gbé e ṣánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ eyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”


Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìlera, láti ọdún méjì-dínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe.


Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjì-dínlógún yìí wá?”


Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì.


Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ. Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè.


Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.


Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá.


Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀; ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀: ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè: yóò wí fúnrarẹ̀.”


Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ,


Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ ààmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan