Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 8:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí, “ ‘kí wọn má ba à rí, àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ó ní, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ àṣírí ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn fún àwọn yòókù, bí òwe bí òwe ni, pé wọn yóo máa wo nǹkan ṣugbọn wọn kò ní mọ ohun tí wọn rí, wọn yóo máa gbọ́ràn ṣugbọn òye ohun tí wọn gbọ́ kò ní yé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 8:10
24 Iomraidhean Croise  

Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.


Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé, ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”


Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn; a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan; bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.


Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’


Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.


“Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.


Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.


Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.


Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, “ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run. Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”


“Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”


Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìhìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,


Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.


Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.


Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀.


Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fihàn nínú ara, tí a dá láre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn angẹli rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan