Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 6:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àwọn kan nínú àwọn Farisi sì wí fún wọn pé, “ki lo de tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Àwọn kan ninu àwọn Farisi sọ pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Awọn kan ninu awọn Farisi si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 6:2
14 Iomraidhean Croise  

“Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá òun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí.


Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́.


Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa.


“Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,


Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”


wọn béèrè pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń rú òfin àtayébáyé àwọn alàgbà? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”


Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”


Wọ́n wí fún pé “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu a máa gbààwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”


Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan