Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 22:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe pa Jesu nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti ṣe pa a; nitoriti nwọn mbẹ̀ru awọn enia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 22:2
12 Iomraidhean Croise  

Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu.


“Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’


“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”


Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á.


Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.


Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.


Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi ààmì òróró yàn,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan