Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 21:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 “Ẹ rí gbogbo nǹkan wọnyi, ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí kò ní sí òkúta kan lórí ekeji tí a kò ní wó lulẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ohun ti ẹnyin nwò wọnyi, ọjọ mbọ̀ li eyi ti a kì yio fi okuta kan silẹ lori ekeji ti a kì yio wó lulẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 21:6
20 Iomraidhean Croise  

“Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘A ó sì fa Sioni tu bí oko Jerusalẹmu yóò di òkìtì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’


nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ”


Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé Olúwa.


Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù, wúrà dídára di àìdán! Òkúta ibi mímọ́ wá túká sí oríta gbogbo òpópó.


Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.


Nítorí náà, nítorí tiyín, ni a ó ṣe ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóò sì di ebè àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.


Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lebanoni, kí iná bá lè jẹ igi kedari rẹ run,


Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà.


Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a yóò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀.”


Jesu dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”


Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti ààmì kín ni yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan