Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 21:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; on ó sì mú kì a pa nínú yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Àwọn òbí yín, ati àwọn arakunrin yín, àwọn ẹbí yín, ati àwọn ọ̀rẹ́ yín, yóo kọ̀ yín, wọn yóo sì pa òmíràn ninu yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 21:16
14 Iomraidhean Croise  

Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé— ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ Wọ́n ti hó lé ọ lórí; Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.


Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ. Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.


“Arákùnrin yóò sì fi arákùnrin fún pípa. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò ṣọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n.


“Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn.


A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”


Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.


A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.


Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu.


Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.”


Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú.


Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.


Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan