Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 20:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Nígbà tí ó yá, ó rán ẹrú rẹ̀ kan sí àwọn alágbàro náà. Ṣugbọn àwọn alágbàro yìí lù ú, wọ́n bá dá a pada ní ọwọ́ òfo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn àgbẹ na, ki nwọn ki o le fun u ninu eso ọgba ajara na: ṣugbọn awọn àgbẹ lù u, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 20:10
32 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Sedekiah ọmọ Kenaana sì dìde, ó sì gbá Mikaiah lójú, ó sì wí pé, “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Olúwa gbà lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”


Olúwa kìlọ̀ fún Israẹli àti Juda nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi paláṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán sí i yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”


Bẹ́ẹ̀ ni Hanuni fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dafidi, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárín ìdí rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.


Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.


“Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì se ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.


Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.


Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.


“Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí. Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.


Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa.


Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.


Wọn kò sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀, tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’


“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!


Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.


Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.


Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín.


Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan