Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 20:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìhìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 20:1
10 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.


Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”


Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,


Jesu dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sinagọgu, àti ní tẹmpili níbi tí gbogbo àwọn Júù ń péjọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀.


Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn Sadusi dìde sí wọn.


Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan