Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Ọpọlọpọ ogun ọrun si yọ si angẹli na li ojijì, nwọn nyìn Ọlọrun, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:13
18 Iomraidhean Croise  

Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.


Mikaiah sì tún wí pé, “Nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ogun ọ̀run dúró ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì rẹ̀.


Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?


Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀


Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.


Nígbà náà ni Ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi tó sọ pé, kí a gbé ògo Olúwa ga láti ibùgbé rẹ̀ wá!


Odò iná ń sàn, ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá, Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un; Ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀. Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀.


Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”


Èyí ni yóò sì ṣe ààmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.


“Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, Àti ní ayé Àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”


Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,


Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fihàn nínú ara, tí a dá láre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn angẹli rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.


Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?


Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.


Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn angẹli púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká: Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọ̀nà ẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan