Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní àkókò náà, àṣẹ kan jáde láti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu pé kí gbogbo ayé lọ kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìjọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O SI ṣe li ọjọ wọnni, aṣẹ ti ọdọ Kesari Augustu jade wá pe, ki a kọ orukọ gbogbo aiye sinu iwe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:1
13 Iomraidhean Croise  

Ọba Ahaswerusi sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù Òkun


Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?”


A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.


Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”


Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìhìnrere mi fún gbogbo ẹ̀dá.


Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.


láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí.


Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,


Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Agabu sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Romu. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣèjọba Kilaudiu.)


Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí ó ṣe pe mo sì ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú: ṣùgbọ́n bí kò bá sí òtítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fi ọ̀ràn mi lọ Kesari.”


Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu fi ọ̀ràn rẹ lọ Augustu, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pe kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Kesari.”


Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.


Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Kesari.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan