Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 18:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ẹẹmeji ni mò ń gbààwẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mò ń dá ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí mo bá gbà.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọ̀sẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 18:12
24 Iomraidhean Croise  

Jehu wí pé, “Wá pẹ̀lú mi; kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.


Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́tí sí i. “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.


“Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’ “Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ.


Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa. Èyí ni mo wí nípa wọn: Wọn kò nígba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.”


Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.”


Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.


“Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò ni èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run.


“Nígbà tí ẹ̀yin bá gbààwẹ̀, ẹ má ṣe fa ojú ro bí àwọn àgàbàgebè ṣe máa ń ṣe nítorí wọn máa ń fa ojú ro láti fihàn àwọn ènìyàn pé àwọn ń gbààwẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín wọn ti gba èrè wọn ní kíkún.


“Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún.


Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”


“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.


Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwa ti ṣe.’ ”


Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.


Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.


Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọpọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi.


Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.


Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀.


Nígbà tí Samuẹli sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Saulu sì wí fún un pé, “Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan