Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 15:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá ń kùn; wọ́n ń sọ pé, “Eléyìí ń kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra, ó tún ń bá wọn jẹun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 15:2
12 Iomraidhean Croise  

Ọmọ ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”


Nígbà tí àwọn Farisi sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èéṣe’ tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun pọ̀?”


Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé,


Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”


Ṣùgbọ́n àwọn Farisi, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pe “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ̀lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”


Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn “ẹlẹ́ṣẹ̀!” ’


Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”


wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”


Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà.


Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan