Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Ó dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 O dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o fi sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ o fi di wiwu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:21
13 Iomraidhean Croise  

Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.


Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí


Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, Yóò jáde; Yóò tọ̀ wá wá bí òjò bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”


Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú.”


Ó sì tún wí pé, “Kín ni èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé?


Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò: gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i.


Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”


Ìṣeféfé yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú?


Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé:


Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan