Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjì-dínlógún yìí wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Ẹ wá wo obinrin yìí, ọmọ Abrahamu, tí Satani ti dè fún ọdún mejidinlogun. Ṣé kò yẹ kí á tú u sílẹ̀ ninu ìdè yìí ní Ọjọ́ Ìsinmi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:16
11 Iomraidhean Croise  

Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.


Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”


Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, “Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ́ ìsinmi.


Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’


Jesu sì wí fún un pé, “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu.


Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí.


Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké.


“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.


wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdẹ̀kùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan