Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 11:51 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili: lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

51 ohun tí ó ṣẹ̀ lórí Abeli títí dé orí Sakaraya tí a pa láàrin ibi pẹpẹ ìrúbọ ati Ilé Ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

51 Lati ẹ̀jẹ Abeli wá, titi o si fi de ẹ̀jẹ Sakariah, ti o ṣegbé lãrin pẹpẹ on tẹmpili: lõtọ ni mo wi fun nyin, A o bère rẹ̀ lọdọ iran yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 11:51
9 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.


Nítorí náà, sọ fún wọn pé ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn.


Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé:


Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.


Nípa ìgbàgbọ́ ní Abeli rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Kaini lọ, nípa èyí tí a jẹ́rìí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́rìí ẹ̀bùn rẹ̀: Àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.


Àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ.


Kì í ṣe bí Kaini, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan