Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 11:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà kan, Jesu wà níbìkan, ó ń gbadura. Nígbà tí ó parí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, kọ́ wa bí a ti í gbadura gẹ́gẹ́ bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, bi o ti ngbadura ni ibi kan, bi o ti dakẹ, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, kọ́ wa bi ãti igbadura, bi Johanu si ti kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 11:1
14 Iomraidhean Croise  

Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára; Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,


Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.


Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”


Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín. Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe, bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.


Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run.


Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”


Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”


Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”


Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.


Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀.


Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan