Luku 10:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní21 Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ. Faic an caibideilYoruba Bible21 Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni. Faic an caibideilBibeli Mimọ21 Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ. Faic an caibideil |