Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 10:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn èyí, Oluwa yan àwọn mejilelaadọrin mìíràn, ó rán wọn ní meji-meji ṣiwaju rẹ̀ lọ sí gbogbo ìlú ati ibi tí òun náà fẹ́ dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 10:1
14 Iomraidhean Croise  

Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbàgbà ilé Israẹli dúró sí, Jaaṣaniah ọmọ Ṣafani sì dúró sí àárín wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.


Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé: “Mú àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrín àwọn ènìyàn wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi.


Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”


“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́: nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;


Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”


Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”


Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan