Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:70 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

70 gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, láti ọjọ́ pípẹ́;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

70 Bi o ti wi li ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́, ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:70
18 Iomraidhean Croise  

Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.


ìhìnrere tí ó ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ nínú ìwé Mímọ́.


Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrín ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Paulu sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah wí pé:


Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.


Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”


Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’


“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, Ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.


“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi, ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.


“Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi.


Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé, tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un.


Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.”


Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”


Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”


Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí: “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,


kí ẹ̀yin lè máa rántí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ sọ ṣáájú, àti òfin Olúwa àti Olùgbàlà wa láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan