Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua. Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Wọ́n sọ fún Joṣua pé “Iranṣẹ yín ni wá.” Joṣua bá dá wọn lóhùn pé, “Ta ni yín, níbo ni ẹ sì ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Iranṣẹ rẹ li awa iṣe. Joṣua si wi fun wọn pe, Tali ẹnyin? nibo li ẹnyin si ti wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:8
9 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ẹni tí ń ṣe olórí ilé, ẹni tí ń ṣe olórí ìlú ńlá, àwọn àgbàgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jehu: “ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù lójú rẹ.”


Tí wọ́n bá dá ọ lóhùn àlàáfíà, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́.


Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”


Àwọn àgbàgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’


Nísinsin yìí, ẹ̀yin di ẹni ègún: Ẹ̀yin kò sì ní kúrò ní gégigégi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.”


Nísinsin yìí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.”


Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gibeoni di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Báyìí ni wọ́n wà títí di òní yìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan