Ọba sì dìde ní òru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò sọ fún yín ohun tí àwọn ará Siria tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sápamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtítọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè, àwa yóò sì wọ inú ìlú lọ.’ ”