Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 8:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Joṣua sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọmọ-ogun pamọ́ sí àárín Beteli àti Ai, sí ìwọ̀-oòrùn ìlú náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Joṣua ṣa nǹkan bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọmọ ogun, ó fi wọ́n pamọ́ sí ààrin Bẹtẹli ati Ai ní apá ìwọ̀ oòrùn Ai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 O si mú to bi ẹgbẹdọgbọ̀n enia, o si fi wọn si ibuba li agbedemeji Betieli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn ilu na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 8:12
7 Iomraidhean Croise  

Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.


Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.


Gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Ai. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà.


Wọ́n sì yan àwọn ọmọ-ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó sápamọ́ sí ìwọ̀-oòrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Joṣua lọ sí àfonífojì.


Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn.


Saulu sì lọ sí ìlú Amaleki ó sì gọ dè wọ́n ní Àfonífojì kan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan