Joṣua 7:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Israẹli. Faic an caibideilYoruba Bible1 Àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí pé ẹnìkan mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, láti inú ẹ̀yà Juda, mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀, inú sì bí OLUWA gidigidi sí àwọn ọmọ Israẹli. Faic an caibideilBibeli Mimọ1 ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli. Faic an caibideil |
Mose sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Eleasari àti Itamari pé, “ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ ṣí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Israẹli le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.