Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 6:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 6:4
33 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.


Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà Òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.” Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.” Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.”


Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”


Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.


Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò fọn ìpè ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Israẹli, Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ Olúwa Ọlọ́run baba yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.”


Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní ààyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”


Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ọmọ Kohati àti àwọn ọmọ Kora sì dìde dúró wọ́n sì sin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá.


Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.”


Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe.


Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.


Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje.


Kí ó ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa, níwájú aṣọ títa ibi mímọ́.


Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀:


Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.


Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.”


Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ.


Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.


Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.”


ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.


Johanu, Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia: Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀;


Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn.


Mo sì rí ààmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn angẹli méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹyìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin.


Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.


Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹmpili wá, ń wí fún àwọn angẹli, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ago ìbínú Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì sí orí ayé.”


Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí.


Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo.


Mo sì rí àwọn angẹli méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.


Àwọn angẹli méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan