Joṣua 6:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní10 Ṣùgbọ́n Joṣua tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kígbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó!” Faic an caibideilYoruba Bible10 Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn yín. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ rárá títí di ọjọ́ tí n óo sọ pé kí ẹ hó, nígbà náà ni ẹ óo tó hó.” Faic an caibideilBibeli Mimọ10 Joṣua si paṣẹ fun awọn enia wipe, Ẹ kò gbọdọ hó bẹ̃li ẹ kò gbọdọ pariwo, bẹ̃li ọ̀rọ kan kò gbọdọ jade li ẹnu nyin, titi ọjọ́ ti emi o wi fun nyin pe, ẹ hó; nigbana li ẹnyin o hó. Faic an caibideil |