Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 5:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Wàyí o, ìdí tí Joṣua fi kọ wọ́n nílà nìyìí: Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Ejibiti jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní aginjù ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ìdí tí Joṣua fi kọ ilà abẹ́ fún wọn ni pé, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ti kú lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Idí rẹ̀ li eyi ti Joṣua fi kọ wọn nilà: gbogbo awọn enia ti o ti Egipti jade wá, ti o ṣe ọkunrin, ani gbogbo awọn ọmọ-ogun, nwọn kú li aginjù, li ọ̀na, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni Egipti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 5:4
8 Iomraidhean Croise  

Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí,


Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.


Ó gbà wá ní ọdún méjì-dínlógójì (38) kí ó tó di wí pé a la Àfonífojì Seredi kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrín àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrín àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí Olúwa ti búra fún wọn.


Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátápátá nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú,


Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì ṣe abẹ akọ òkúta, ó sì kọ àwọn ọmọ Israẹli ní ilà, ní Gibiati-Haralotu.


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Ejibiti ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Ejibiti ni wọn kò kọ ní ilà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan