Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 5:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Mana kò dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn ọmọ Israẹli kò rí i kó mọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ninu èso ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọ́n jẹ ninu èso ilẹ̀ Kenaani ní gbogbo ọdún náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Manna si dá ni ijọ́ keji lẹhin igbati nwọn ti jẹ okà gbigbẹ ilẹ na; awọn ọmọ Israeli kò si ri manna mọ́; ṣugbọn nwọn jẹ eso ilẹ Kenaani li ọdún na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 5:12
9 Iomraidhean Croise  

Àwọn ará Israẹli jẹ manna fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kenaani ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ; Wọ́n jẹ manna títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbègbè Kenaani.


Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.


Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa.


Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”


Ní ọjọ́ kejì Àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan