Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 5:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ní ọjọ́ kejì Àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Nwọn si jẹ ọkà gbigbẹ ilẹ na ni ijọ́ keji lẹhin irekọja, àkara alaiwu, ọkà didin li ọjọ̀ na gan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 5:11
7 Iomraidhean Croise  

Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.


Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.


Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa.


Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà (oṣù kẹrin) nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gilgali ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko, àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ọdún Àjọ ìrékọjá.


Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan