Joṣua 4:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.” Faic an caibideilYoruba Bible7 Nígbà náà, ẹ óo dá wọn lóhùn pé omi odò Jọdani pín sí meji níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA nígbà tí wọn gbé e kọjá odò náà. Nítorí náà, àwọn òkúta wọnyi yóo jẹ́ ohun ìrántí ayérayé fún àwọn ọmọ Israẹli.” Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Nigbana li ẹnyin o da wọn lohùn pe, Nitori a ke omi Jordani niwaju apoti majẹmu OLUWA; nigbati o rekọja Jordani, a ke omi Jordani kuro: okuta wọnyi yio si jasi iranti fun awọn ọmọ Israeli lailai. Faic an caibideil |
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ, dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá, ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí, dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà. Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n, ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;