Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 4:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 kí ó sì jẹ́ ààmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Kí èyí lè jẹ́ ohun ìrántí fun yín, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ yín ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ki eyi ki o le jẹ́ àmi lãrin nyin, nigbati awọn ọmọ nyin ba bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la, wipe, Èredi okuta wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 4:6
19 Iomraidhean Croise  

À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run àwọn baba wa tí sọ fún wa ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.


Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.


“Ọjọ́ òní ni yóò sì máa ṣe ọjọ́ ìrántí fún yín, ẹ́yin yóò sì máa láàrín àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe ní àjọ fún Olúwa; ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé.


“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú.


Ṣíṣe èyí yóò wà fún ààmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ààmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.


“Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.


Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.


Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà, àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ. Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa, fún ààmì ayérayé, tí a kì yóò lè parun.”


Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ààmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.


Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ ààmì láàrín wa: ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín.”


Èyí ni àwo tùràrí àwọn tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí ẹ gún àwo tùràrí yìí, kí ẹ sì fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, wọ́n jẹ́ mímọ́ nítorí pé wọ́n ti mú wọn wá síwájú Olúwa. Kí wọ́n jẹ́ ààmì fún àwọn ọmọ Israẹli.”


Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”


Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.


Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàrín àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’


Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’


ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan