Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Joṣua bá sọ fún àwọn alufaa pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu náà kí ẹ sì máa lọ níwájú àwọn eniyan yìí.” Wọ́n bá gbé Àpótí Majẹmu náà, wọ́n sì ń lọ níwájú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:6
11 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli dé, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí,


Gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli sì wá, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.


Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn; wọn yóò fọ láti ẹnu ibodè, wọn yóò sì jáde lọ. Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn, Olúwa ni yóò sì ṣe olórí wọn.”


Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn.


Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé,


níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.


Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e.


Joṣua sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Olúwa yóò ṣe ohun ìyanu ní àárín yín.”


Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose.


Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan