Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:16
31 Iomraidhean Croise  

Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí Àfonífojì Siddimu (Òkun iyọ̀).


Baana ọmọ Ahiludi, ní Taanaki àti Megido, àti ní gbogbo Beti-Ṣeani tí ń bẹ níhà Saretani ní ìsàlẹ̀ Jesreeli, láti Beti-Ṣeani dé Abeli-Mehola títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jokimeamu;


Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani lágbedeméjì Sukkoti àti Saretani.


Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn.


Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?


Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi; Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.


Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.


Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.


Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi; Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ


Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun, Ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.


Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.


Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé Òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi Òkun sì pínyà,


àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú Òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.


Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli la Òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn.


Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.


Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi Òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.


Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá.


Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ, Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.


Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, Olúwa? Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí? Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun tí ìwọ fi ń gun ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?


“ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,


Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose sọ fún gbogbo Israẹli ní aginjù, aginjù ìlà-oòrùn Jordani, ni Arabah: ní òdìkejì Ṣufi, ní àárín Parani àti Tofeli, Labani, Haserotu àti Disahabu.


Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah pẹ̀lú, àti Jordani gẹ́gẹ́ bí òpin ilẹ̀ rẹ̀, láti Kinnereti lọ títí dé Òkun pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah, àní Òkun iyọ̀, ní ìsàlẹ̀ àwọn orísun Pisga ní ìhà ìlà-oòrùn.


Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.


Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀,


Láti Janoa ó yípo lọ sí gúúsù sí Atarotu àti Naara, ó sì dé Jeriko, ó sì pín sí odò Jordani.


Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Olúwa, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹsẹ̀ bọ odò Jordani, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbá jọ bí òkìtì kan.”


Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Israẹli rékọjá odò Jordani ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’


Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Amori ti ìlà-oòrùn Jordani àti gbogbo àwọn ọba Kenaani tí ń bẹ létí Òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú Jordani gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Israẹli títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pami, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojúkọ àwọn ọmọ Israẹli.


Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan