Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Olúwa, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹsẹ̀ bọ odò Jordani, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbá jọ bí òkìtì kan.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:13
13 Iomraidhean Croise  

Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ Olúwa ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.


Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.


Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi; Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ


Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.


Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.


Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.


Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já, ó sì da àwọn omi ńlá ru.


Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”


Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń gòkè lọ sí Jordani ṣáájú u yín.


Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan