Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 24:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 24:5
13 Iomraidhean Croise  

Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀


Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.


Àwọn ọmọ Israẹli sì rìn láti Ramesesi lọ sí Sukkoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.


Ó sì ní òpin irínwó ọdún ó le ọgbọ̀n (430), ní ọjọ́ náà gan an, ni ó sì ṣe tí gbogbo ogun Olúwa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.


Àti pé ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn.


Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”


Àwọn ni ó bá Farao ọba Ejibiti sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni Ejibiti, àní Mose àti Aaroni yìí kan náà ni.


Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan