Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 23:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ súnmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe títí di òní.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ṣugbọn ki ẹnyin faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe titi di oni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 23:8
11 Iomraidhean Croise  

Ó súnmọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mose.


Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa.


Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.


Bí ẹ bá fi ara balẹ̀ kíyèsi àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé: Láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìímú ṣinṣin:


Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀: ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin.


Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Ejibiti wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrín yín.


Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láààyè lónìí.


Bí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu.


Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, láti dìímú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”


Ẹ má ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ́kù láàrín yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn.


“Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojúkọ yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan