Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 23:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ẹ má ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ́kù láàrín yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 kí ẹ má baà darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, kí ẹ má baà máa bọ àwọn oriṣa wọn, tabi kí ẹ máa fi orúkọ wọn búra, tabi kí ẹ máa sìn wọ́n, tabi kí ẹ máa foríbalẹ̀ fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ki ẹnyin ki o má ṣe wá sãrin awọn orilẹ-ède wọnyi, awọn wọnyi ti o kù pẹlu nyin; ki ẹnyin má ṣe da orukọ oriṣa wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe fi wọn bura, ẹ má ṣe sìn wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe tẹriba fun wọn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 23:7
23 Iomraidhean Croise  

Wọ́n sìn òrìṣà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.”


Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rimoni láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rimoni, kí Olúwa dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”


“Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n,


Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn. Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.


Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.


“Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà, kí a má ṣe gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín.


Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn gbé ni ilẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò mú ọ dẹ́ṣẹ̀ sí mi: nítorí bí ìwọ bá sin òrìṣà wọn, èyí yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fun ọ nítòótọ́.”


Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.


Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi.


“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.


Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀; ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́


àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé, àwọn tí ń sin ogun ọ̀run, àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra, tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.


pẹ̀lú Nebo pẹ̀lú Baali-Meoni, (Wọ́n pàrọ̀ orúkọ wọn) àti Sibma. Wọ́n sì sọ ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.


“ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé.


Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.”


Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí.


Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.


Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan.


Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká;


“Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù láàrín yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀,


Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan