Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 23:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì ṣọ́ra láti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mose, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sinu ìwé òfin Mose. Ẹ kò gbọdọ̀ yẹ ẹsẹ̀ kúrò ninu wọn sí ọ̀tún tabi sí òsì,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Nitorina ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwé ofin Mose, ki ẹnyin ki o má ṣe yipada kuro ninu rẹ̀ si ọwọ́ ọtún tabi si ọwọ́ òsi;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 23:6
14 Iomraidhean Croise  

kí o sì wòye ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ,


Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.


Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.


Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òtítọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn; wọn kò sì náání mi, ní Olúwa wí.


Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.


Ẹ rí i pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ẹ má ṣe fi kún un, ẹ má sì ṣe yọ kúrò níbẹ̀.


Kí ó má ba à lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ ọba pẹ́ títí ní Israẹli.


Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.


Torí èyí, ẹ ṣọ́ra láti máa ṣe ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín tí pa ní àṣẹ fún un yín; ẹ má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì.


Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín.


Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan